CAC Hymn 815: Asegun ati Ajogun ni a je
- 11.11.11.11. & Ref.
Awa ju eniti o segun lo, nipa eniti o fe wa. – Rom. 8:3 7.
1 f Asegun ati ajogun ni a je,
Nipa eje Kristi a ni isegun;
B’Oluwa je tiwa, a ki yo subu;
Ko s’ohun to le bori agbara Re.
f Asegun ni wa, nipa eje Jesu;
Baba fun wa ni ‘segun, nipa eje Jesu;
Eni t’apa felese
Sibe, O wa, O njoba;
ff Awa ju asegun lo,
Awa ju asegun lo.
2 f A nlo l’oruko Olorun Israel
Lati segun ese at’aisododo;
Kise fun wa, sugbon Tire ni iyin
Fun ‘gbala at’isegun ta f’eje ra.
3 f Eni t’O ba si segun li ao fi fun,
Lati je manna to t’orun wa nihin
L’orun yo si gbe imo ‘pe asegun,
Yo wo ‘so funfun, yo si dade wura.
Amin